A bá ọmọdébìnrin Démiládé Agbédègbẹyọ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí ó ṣe gbọ́ ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ó sì ṣàlàyé pé ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ọ̀hún ni àwọn òbí rẹ̀ máa ń bá a sọ nílé lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ kó mọ́ ọn lẹ́nu.

A bá àwọn òbí rẹ̀ náà sọ̀rọ̀, wọ́n sì sọ bí ọmọ náà ṣe jẹ́ àkàndá ọmọ, tó sì ń yára há ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan.