A dé ilé àwọn mọ̀lẹ́bí Òbílànà láti bá wọn kẹ́dùn àti láti gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an tó mú èèyàn márùn-ún nínú mẹ́fà dèrò ọ̀run alákeji lẹ́yìn oúnjẹ tí wọ́n jẹ.
A bá ọ̀kan nínú àwọn mọ̀lẹ́bí náà sọ̀rọ̀, a bá ẹnìkan tó jẹ́ ará àdúgbò wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú, wọ́n sì sọ irú ẹni tí Òbílànà jẹ́ nígbà ayé rẹ̀.
A bá aṣojú ilé ìwòsàn ìjọba FMC ti ìlú Abẹ́òkúta náà sọ̀rọ̀, àwọn pàápàá sì bá mọ̀lẹ́bí Òbílànà kẹ́dùn lórí àjálù burúkú náà.
All rights reserved. This material, and other digital content on this website, may not be reproduced, published, broadcast, rewritten or redistributed in whole or in part without prior express written permission from PUNCH.
Contact: theeditor[at]punchng.com