A bá àwọn ará ìlú sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀wọ́ngógó epo àti náírà tuntun ṣe kàn wọ́n sí, oníkálukú ló fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn, tí wọ́n sì mú ọ̀kan-ò-jọ̀kan àbá wá lórí bí a ṣe lè dẹ́kun ìṣòro náà láìpẹ́ jọjọ.